2 Samuel 23

Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi

1Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi.

“Dafidi ọmọ Jese,
àní ọkùnrin tí a ti gbéga,
ẹni ààmì òróró Ọlọ́run Jakọbu,
àti olórin dídùn Israẹli wí pé:

2“Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi.
3Ọlọ́run Israẹli ni,
àpáta Israẹli sọ fún mi pé:
‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo,
tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
4Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là,
òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu,
nígbà tí koríko tútù
bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’

5“Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run,
ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,
tí a túnṣe nínú ohun gbogbo,
tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi,
ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà.
6Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì,
nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.
7Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò
fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká;
wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.”

Iṣẹ́ àwọn alágbára tí Dafidi ní

8 aWọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní:

Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn Balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.

9Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò. 10Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.

11Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili: àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini. 12Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá.

13Mẹ́ta nínú àwọn ọgbọ̀n ìjòyè sọ̀kalẹ̀, wọ́n sì tọ Dafidi wá ní àkókò ìkórè nínú ihò Adullamu: ọ̀wọ́ àwọn Filistini sì dó sí Àfonífojì Refaimu. 14Dafidi sì wà nínú odi, ibùdó àwọn Filistini sì wà ní Bẹtilẹhẹmu nígbà náà. 15Dafidi sì ń pòǹgbẹ, ó wí báyìí pé, “Ta ni yóò fún mi mu nínú omí kànga tí ń bẹ ní Bẹtilẹhẹmu, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè.” 16Àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta sì la ogún àwọn Filistini lọ, wọ́n sì fa omi láti inú kànga Bẹtilẹhẹmu wá, èyí tí ó wà ní ìhà ẹnu-bodè, wọ́n sì mú tọ Dafidi wá: òun kò sì fẹ́ mu nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tú u sílẹ̀ fún Olúwa. 17Òun sì wí pé, “Kí a má rí, Olúwa, tí èmi ó fi ṣe èyí; ṣé èyí ni ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tí ó lọ tí àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ́wọ́?” Nítorí náà òun kò sì fẹ́ mú un.

Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe.

18Abiṣai, arákùnrin Joabu, ọmọ Seruiah, òun náà ni pàtàkì nínú àwọn mẹ́ta. Òun ni ó sì gbé ọ̀kọ̀ rẹ̀ sókè sí ọ̀ọ́dúnrún ènìyàn, ó sì pa wọ́n, ó sì ní orúkọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. 19Ọlọ́lá jùlọ ni òun jẹ́ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: ó sì jẹ́ olórí fún wọn: ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ìṣáájú.

20Benaiah, ọmọ Jehoiada, ọmọ akọni ọkùnrin kan tí Kabṣeeli, ẹni tí ó pọ̀ ní iṣẹ́ agbára, òun pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu; ó sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ó sì pa kìnnìún kan nínú ihò lákoko òjò-dídì. 21Ó sì pa ará Ejibiti kan, ọkùnrin tí ó dára láti wò: ará Ejibiti náà sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀: ṣùgbọ́n Benaiah sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ, pẹ̀lú ọ̀pá ní ọwọ́, ó sì gba ọ̀kọ̀ náà lọ́wọ́ ará Ejibiti náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa á. 22Nǹkan wọ̀nyí ní Benaiah ọmọ Jehoiada ṣe, ó sì ní orúkọ nínú àwọn ọkùnrin alágbára mẹ́ta náà. 23Nínú àwọn ọgbọ̀n (30) náà, òun ní ọlá jùlọ, ṣùgbọ́n òun kò tó àwọn mẹ́ta ti ìṣáájú. Dafidi sì fi í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀.

24Ọ̀kan nínú àwọn ọgbọ̀n (30) náà:

Asaheli arákùnrin Joabu sì Jásí
Elhanani ọmọ Dodo ti Bẹtilẹhẹmu;
25Ṣamma ará Haroditi,
Elika ará Harodi.
26Helesi ará Palti,
Ira ọmọ Ikẹsi ará Tekoa;
27Abieseri ará Anatoti,
Sibekai ará Huṣati;
28Salmoni ará Ahohi,
Maharai ará Netofa;
29Heledi ọmọ Baanah, ará Netofa,
Ittai ọmọ Ribai to Gibeah ti àwọn ọmọ Benjamini;
30Benaiah ará Piratoni,
Hiddai ti Àfonífojì Gaaṣi,
31Abi-Alboni ará Arbati,
Asmafeti Barhumiti;
32Eliaba ará Ṣaalboni,
àwọn ọmọ Jaṣeni,
Jonatani;
33ọmọ Ṣamma ará Harari,
Ahiamu ọmọ Ṣarari ará Harari;
34Elifeleti ọmọ Ahasbai, ọmọ ará Maakati,
Eliamu ọmọ Ahitofeli ará Giloni;
35Hesro ará Karmeli,
Paarai ará Arba;
36Igali ọmọ Natani ti Ṣoba,
Bani ará Gadi;
37Seleki ará Ammoni,
Naharai ará Beeroti, ẹni tí ń ru ìhámọ́ra Joabu ọmọ Seruiah;
38Ira ará Itri,
Garebu ará Itri.
39Uriah ará Hiti.

Gbogbo wọn jẹ́ mẹ́tà-dínlógójì.
Copyright information for YorBMYO